Nicotto Town



わかっちゃいるけど ひゃくよんぢうはち

luglio 11 giovedi ☁︎ 29/24℃


Angélique Kpasseloko Hinto Hounsinou Kandjo Manta Zogbin Kidjo,[1][2][3] known as Angélique Kidjo (born July 14, 1960), jẹ́ gbajúmọ̀ olórin, òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, ajìjàǹgbara ọmọbìnrin láti orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin Beninese, tí ó tún míràn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ olórin-bìnrin nípa Ìṣẹ̀wọ́ kọrin àti fídíò orin lọ́nà àrà. Lọ́dún 2007, gbajúgbajà ìwé ìròyìn àgbáyé nì, Time Magazine júwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú olórin-bìnrin nílẹ̀ Áfíríkà, "Africa's premier diva".[4]

Gbajúmọ̀ nínú àwọn orin rẹ̀ máa ń dá lórí ẹ̀yà orin tí wọ́n ń pè ní Afropop, Caribbeanzouk, Congolese rumba, jazz, Orin ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, àti Latin; bẹ́ẹ̀, àwọn orin rẹ̀ máa ń dá lé àwọn olórin àtijó tí ó kúndùn láti ìgbà èwe rẹ̀, àwọn olórin bí i Bella Bellow, James Brown, Nina Simone, Aretha Franklin, Celia Cruz, Jimi Hendrix, Miriam Makeba àti Carlos Santana. Ó ti kọ àwọn ẹ̀dà orin tí olórin àtijó George Gershwin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Summertime", Ravel's Boléro, Jimi Hendrix's "Voodoo Child" àti the Rolling Stones' "Gimme Shelter", bẹ́ẹ̀ náà dára pọ̀ mọ́ Dave Matthews àti Dave Matthews Band, Kelly Price, Alicia Keys, Branford Marsalis, Ziggy Marley, Philip Glass, Peter Gabriel, Bono, Carlos Santana, John Legend, Herbie Hancock, Josh Groban, Dr John, the Kronos Quartet, Yemi Alade, Cassandra Wilson àti gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé orílẹ̀-èdè Indonesia, Anggun. Lára àwọn orin Kidjo tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni "Agolo", "We We", "Adouma", "Wombo Lombo", "Afirika", "Batonga", àti ọ̀wọ́ orin "Malaika" tirẹ̀. Àwo orin rẹ̀, Logozo ni wọ́n yàn nípò kẹtàdínlógójì nínú àwọn gbajúmọ̀ orin àlùjó tó gbajúmọ̀ jùlọ ní àgbáyé, gbajúmọ̀ ìwé-ìròyìn àgbáyé nì, Vice Magazine ló ṣe agbátẹrù rẹ̀ ní ìkànnì ayélujára wọn.[5]





Copyright © 2024 SMILE-LAB Co., Ltd. All Rights Reserved.